97.The Power, Fate

  1. Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì
  2. Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Òru Abiyì
  3. Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù lọ
  4. Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan
  5. Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́