96.The Clot

  1. Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá
  2. Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì
  3. Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ
  4. Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn
  5. Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n
  6. Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-àlà
  7. nítorí pé ó ríra rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀
  8. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá
  9. Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń kọ̀
  10. fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun
  11. Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)
  12. tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)
  13. Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i
  14. Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni)
  15. Bẹ́ẹ̀ ni (Allāhu ń rí i.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí i lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná)
  16. àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀
  17. Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀
  18. Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná
  19. Rárá o, má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o súnmọ́ (Allāhu)