95.The Fig

  1. Allāhu búra pẹ̀lú èso tīn àti èso zaetūn
  2. Ó tún búra pẹ̀lú àpáta Sīnīn
  3. Ó tún búra pẹ̀lú ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí
  4. Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ
  5. Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná)
  6. Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn
  7. Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)
  8. Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni