94.The Consolation

  1. Ṣé A ò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí
  2. A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ
  3. èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn. àmọ́ tí onítọ̀ún padà gba ’Islām ìbáà jẹ́ pé ó gbà á ní òwúrọ̀
  4. A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ
  5. Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira
  6. Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́
  7. Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ọ̀kan), gbìyànjú (òmíràn)
  8. Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí