93.The Morning Hours

  1. (Allāhu búra pẹ̀lú) ìyálẹ̀ta
  2. Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú
  3. Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ
  4. Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé lọ
  5. Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i
  6. Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé
  7. Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́
  8. Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀
  9. Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí)
  10. Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn)
  11. Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde