92.The Night

  1. (Allāhu) búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú
  2. Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n
  3. Ó tún búra pẹ̀lú Ẹni tí Ó dá akọ àti abo
  4. Dájúdájú iṣẹ́ yín, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni
  5. Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu)
  6. (tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní òdodo
  7. A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un
  8. Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni t’ó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run
  9. (tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní irọ́
  10. A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un
  11. Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá já bọ́ (sínú Iná)
  12. Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà
  13. Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé
  14. Nítorí náà, Mo ti fi Iná eléjò fòfò kìlọ̀ fun yín
  15. Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú
  16. ẹni tí ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i
  17. Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu)
  18. ẹni t’ó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀)
  19. Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni
  20. bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ
  21. Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rẹ̀)