90.The City

  1. Èmi (Allāhu) búra pẹ̀lú ìlú yìí
  2. Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀)
  3. (Mo tún) búra pẹ̀lú òbí àti ohun t’ó bí
  4. Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro
  5. Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni
  6. Ó (sì) ń wí pé: "Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì s.a.w)
  7. Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni
  8. Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un
  9. Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)
  10. A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n
  11. Kò sì mú àkàbà ìgbàlà gùn
  12. Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ àkàbà ìgbàlà
  13. (Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú
  14. Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi
  15. (Ó lè jẹ́) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí
  16. tàbí mẹ́kùnnú, ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀
  17. Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe
  18. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún
  19. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì
  20. A máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá