88.The Overwhelming

  1. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun t’ó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ
  2. Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn
  3. Oníṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni wọ́n nílé ayé)
  4. Wọ́n máa wọ inú Iná t’ó gbóná janjan (ní ọ̀run)
  5. Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi gbígbóná mu
  6. Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ
  7. Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi
  8. Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn
  9. nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀
  10. (Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga
  11. Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀
  12. Omi ìṣẹ́lẹ̀rú t’ó ń ṣàn wà nínú rẹ̀
  13. Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀
  14. àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn)
  15. àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn
  16. àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká
  17. Nítorí náà, ṣé wọn kò wo ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni
  18. àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè
  19. àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀)
  20. àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ ní gban̄sasa
  21. Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí
  22. Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn
  23. àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́
  24. Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó tóbi jùlọ
  25. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà
  26. Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn