87.The Most High

  1. Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ
  2. Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba
  3. Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà
  4. Ẹni tí Ó mú koríko tútù (hù) jáde
  5. Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ t’ó dúdú
  6. Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé
  7. Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun t’ó pamọ́
  8. Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ
  9. Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò
  10. Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí
  11. Olórí-burúkú sì máa takété sí i
  12. (Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná t’ó tóbi
  13. Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà)
  14. Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn rẹ̀) ti jèrè
  15. Ó tún rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun
  16. Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé
  17. Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé
  18. Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́
  19. tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā