86.The Morning Star

  1. (Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ
  2. Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Tọ̄riƙ
  3. Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni)
  4. Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika)
  5. Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀
  6. Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi t’ó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́
  7. Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin
  8. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
  9. ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́
  10. Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un
  11. Allāhu búra pẹ̀lú sánmọ̀ t’ó ń rọ òjò ní ọdọọdún
  12. Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ t’ó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso)
  13. Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́)
  14. Kì í sì ṣe àwàdà
  15. Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an
  16. Èmi náà sì ń déte gan-an
  17. Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀