85.The Constellations

  1. (Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀
  2. Ó tún búra pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn
  3. Ó tún búra pẹ̀lú olùjẹ́rìí àti ohun t’ó jẹ́rìí sí
  4. A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó gbẹ́ kòtò (iná)
  5. (ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò)
  6. (Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀
  7. Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  8. Kò sì sí kiní kan tí wọ́n torí rẹ̀ jẹ wọ́n níyà bí kò ṣe pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ọlọ́pẹ́
  9. Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan
  10. Dájúdájú àwọn t’ó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná t’ó ń jò sì wà fún wọn
  11. Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá
  12. Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le
  13. Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde)
  14. Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá)
  15. Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ
  16. Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́
  17. Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ
  18. (ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd
  19. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo nírọ́
  20. Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn
  21. Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé
  22. tí ó wà nínú wàláà tí À ń ṣọ́