84.The Splitting Open

  1. Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
  2. ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ –
  3. àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú
  4. ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo
  5. – ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ – (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)
  6. Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀
  7. Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀
  8. láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn
  9. Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú
  10. Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀
  11. láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun
  12. Ó sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò fòfò
  13. Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé)
  14. Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni)
  15. Rárá (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀
  16. Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwòǹpapa
  17. Mo tún búra pẹ̀lú òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀
  18. Mo tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀)
  19. Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan
  20. Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo
  21. Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀
  22. Rárá, ńṣe ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é nírọ́
  23. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn)
  24. Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro
  25. Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin ń bẹ fún wọn