83.Defrauding

  1. Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù
  2. àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún
  3. nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù
  4. Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde
  5. ní Ọjọ́ ńlá kan
  6. Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde nàró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  7. Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni ibi kúkú wà nínú Sijjīn
  8. Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Sijjīn
  9. Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn)
  10. Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́
  11. àwọn t’ó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́
  12. Kò sì sí ẹni t’ó ń pè é nírọ́ àfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀
  13. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)
  14. Rárá kò rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ibi l’ó jọba lórí ọkàn wọn
  15. Ní ti òdodo, dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn
  16. Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm
  17. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè nírọ́
  18. Bẹ́ẹ̀ ni. Dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn
  19. Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ ‘illiyyūn
  20. Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn)
  21. Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i
  22. Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn
  23. Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn
  24. Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn
  25. Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí
  26. Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn
  27. Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà)
  28. (Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu
  29. Dájúdájú àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín
  30. Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn adẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́
  31. Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí
  32. Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà
  33. Àwa kò sì rán wọn níṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn
  34. Nítorí náà, ní òní àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín
  35. Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn
  36. Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)