82.The Cleaving

  1. Nígbà tí sánmọ̀ bá fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
  2. àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri
  3. àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn
  4. àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè
  5. (nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀)
  6. Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé
  7. Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn
  8. Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́
  9. Ní ti òdodo, ńṣe l’ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́
  10. Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín
  11. (Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá
  12. Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
  13. Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn
  14. Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm
  15. Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san
  16. Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀
  17. Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san
  18. Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san
  19. (Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu