81.The Overthrowing

  1. Nígbà tí Wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù
  2. àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri
  3. àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù)
  4. àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì
  5. àti nígbà tí Wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ
  6. àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná
  7. àti nígbà tí Wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
  8. àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé
  9. ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún
  10. àti nígbà tí Wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀
  11. àti nígbà tí Wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè
  12. àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò
  13. àti nígbà tí Wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo)
  14. (nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi)
  15. Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ t’ó ń yọ ní alẹ́, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán
  16. (ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ t’ó ń rìn lọ rìn bọ̀, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn
  17. Mo tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ
  18. Mo tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀
  19. Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé
  20. alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá
  21. ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán
  22. Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè
  23. Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere
  24. Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i)
  25. Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀
  26. Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ
  27. Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá
  28. (Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé
  29. Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá