80.He frowned

  1. (Ànábì s.a.w.) fajú ro, ó sì pẹ̀yìn dà
  2. nítorí pé afọ́jú wá bá a
  3. Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
  4. tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní
  5. Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀
  6. òun ni ìwọ tẹ́tí sí
  7. Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
  8. Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, t’ó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú)
  9. tí ó sì ń páyà (Allāhu)
  10. ìwọ kò sì kọbi ara sí i
  11. Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí
  12. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀
  13. (Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé
  14. A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
  15. ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika)
  16. àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere
  17. Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ
  18. Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀
  19. Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀
  20. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un
  21. Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè
  22. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde
  23. Ẹ gbọ́, ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un
  24. Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀
  25. Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀
  26. Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn
  27. A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀
  28. àti èso àjàrà àti kànnáfùrù
  29. àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù
  30. àti àwọn ọgbà t’ó kún fún igi
  31. àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde)
  32. (Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín
  33. Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀
  34. ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀
  35. àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀
  36. àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀
  37. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn t’ó máa tó o ó rán
  38. Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀
  39. Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú
  40. Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀
  41. Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀
  42. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀