79.Those who drag forth

  1. Allāhu búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́
  2. Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  3. Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀
  4. Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà
  5. Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń ṣètò ilé ayé
  6. Ní ọjọ́ tí ìfọn àkọ́kọ́ fún òpin ayé máa mi gbogbo ayé tìtì pẹ̀lú ohùn igbe
  7. Ìfọn kejì fún Àjíǹde sì máa tèlé e
  8. Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn
  9. Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ
  10. Wọn yóò wí pé: "Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)
  11. Ṣé nígbà tí a ti di eegun t’ó kẹfun tán
  12. Wọ́n wí pé: "Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni t’ó pè é nírọ́)
  13. Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni
  14. Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa
  15. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ
  16. (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonífojì mímọ́, Tuwā
  17. Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà
  18. Kí o sì sọ pé: "Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí
  19. Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, kí o páyà (Rẹ̀)
  20. Ó sì fi àmì t’ó tóbi hàn án
  21. (Àmọ́) ó pè é lópùrọ́. Ó sì yapa rẹ̀
  22. Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó)
  23. Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì
  24. Ó sì wí pé: "Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ
  25. Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́)
  26. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu)
  27. Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ
  28. Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé t’ó gún régé
  29. Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde
  30. Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn
  31. Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀
  32. Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin
  33. Ìgbádùn ni fun yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín
  34. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé
  35. ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun t’ó ṣe níṣẹ́
  36. Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni t’ó ríran
  37. Nítorí náà, ní ti ẹni t’ó bá tayọ ẹnu-àlà
  38. tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé
  39. dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀)
  40. Ní ti ẹni tí ó bá páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀)
  41. dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀)
  42. Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: "Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀
  43. Ọ̀nà wo ni ìwọ lè fi ní (ìmọ̀) ìrántí rẹ̀ ná
  44. Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà
  45. Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni t’ó ń páyà rẹ̀
  46. Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò lò tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan lọ (nílé ayé)