78.The Announcement

  1. Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná
  2. Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni
  3. èyí tí wọ́n ń yapa ẹnu sí
  4. Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀
  5. Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀
  6. Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí
  7. àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)
  8. A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo)
  9. A ṣe oorun yín ní ìsinmi
  10. A tún ṣe alẹ́ ní ìbora
  11. A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu
  12. A tún mọ sánmọ̀ méje t’ó lágbára sókè yín
  13. A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ t’ó ń tàn gbòlà
  14. Àti pé A sọ omi t’ó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò
  15. nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde
  16. pẹ̀lú àwọn ọgbà t’ó kún digbí fún n̄ǹkan oko
  17. Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan
  18. (Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ
  19. Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn
  20. Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná
  21. Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà
  22. (Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ
  23. Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ
  24. Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀
  25. àyàfi omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀
  26. (Ó jẹ́) ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn)
  27. Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́
  28. Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́ gan-an
  29. Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan
  30. Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fun yín bí kò ṣe ìyà
  31. Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
  32. Àwọn ọgbà àti èso àjàrà
  33. àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí
  34. àti ife ọtí t’ó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn)
  35. Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀
  36. (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn)
  37. (Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀
  38. Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ t’ó ṣe wẹ́kú
  39. Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà)
  40. Dájúdájú A fi ìyà t’ó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fun yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà)