38.The letter Saad
- Sọ̄d. (Allāhu búra pẹ̀lú) al-Ƙur’ān, tírà ìrántí
- Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wà nínú ìgbéraga àti ìyapa (òdodo)
- Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n kígbe tòò nígbà tí kò sí ibùsásí kan
- Wọ́n ṣèèmọ̀ pé olùkìlọ̀ kan nínú wọn wá bá wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: "Èyí ni òpìdán, òpùrọ́
- Ṣé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí A óò máa jọ́sìn fún ni? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu
- Àwọn aṣíwájú nínú wọn sì lọ (káàkiri láti wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn wọn) pé: "Ẹ máa bá (ìbọ̀rìṣà) lọ, kí ẹ sì dúró ṣinṣin ti àwọn òrìṣà yín. Dájúdájú èyí (jíjẹ́ ọ̀kan ṣoṣo Allāhu) ni n̄ǹkan tí wọ́n ń gbà lérò (láti fi pa àwọn òrìṣà yín run)
- Àwa kò gbọ́ èyí nínú ẹ̀sìn ìkẹ́yìn (ìyẹn, ẹ̀sìn kristiẹniti) . Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àdápa irọ́
- Ṣé Wọ́n sọ Ìrántí kalẹ̀ fún un láààrin wa ni?" Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa Ìrántí Mi (tí Mo sọ̀kalẹ̀ ni). Rárá, wọn kò tí ì tọ́ ìyà Mi wò ni
- Tàbí (ṣé) àwọn ni wọ́n ni àwọn àpótí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ, Alágbára, Ọlọ́rẹ
- Tàbí tiwọn ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin méjèèjì? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wọn wá àwọn ọ̀nà láti fi gùnkè wá (bá Wa)
- A máa ṣẹ́gun ọmọ ogun t’ó wà níbẹ̀ yẹn nínú ọmọ ogun oníjọ
- Àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti Fir‘aon, eléèkàn, wọ́n pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn
- Ìjọ Thamūd, ìjọ Lūt àti àwọn ará ’Aekah, àwọn wọ̀nyẹn (tún ni) àwọn ìjọ (t’ó pe òdodo nírọ́)
- Kò sí ẹnì kan nínú wọn tí kò pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà Mi sì kò lé wọn lórí
- Àwọn wọ̀nyí kò retí kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan, tí kò níí sí ìdápadà (tàbí ìdádúró) kan fún un (t’ó bá dé)
- Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, yára fi ìwé iṣẹ́ wa (àti ẹ̀san wa) lé wa lọ́wọ́ ṣíwájú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́
- Ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ. Kí o sì ṣèrántí ìtàn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) Dāwūd, alágbára. Dájúdájú ó jẹ́ olùronúpìwàdà
- Dájúdájú Àwa tẹ àwọn àpáta lórí ba tí wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ (fún Allāhu) ní àṣálẹ́ àti nígbà tí òòrùn bá yọ
- Àti àwọn ẹyẹ náà, A kó wọn jọ fún un. Ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ (láti ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu)
- Àti pé A fún ìjọba rẹ̀ ní agbára. A sì fún un ní ipò Ànábì àti ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ àti ìdájọ́
- Ǹjẹ́ ìró àwọn oníjà ti dé ọ̀dọ̀ rẹ; nígbà tí wọ́n pọ́n ògiri ilé ìjọ́sìn
- Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Dāwūd, ẹ̀rù bà á láti ara wọn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Oníjà méjì (ni wá). Apá kan wa tayọ ẹnu-àlà sí apá kan. Nítorí náà, dájọ́ láààrin wa pẹ̀lú òdodo. Má ṣàbòsí. Kí o sì tọ́ wa sí ọ̀nà tààrà
- Dájúdájú èyí ni arákùnrin mi. Ó ní abo ewúrẹ́ mọ́kàndín-lọ́gọ́rùn-ún. Èmi sì ní abo ewúrẹ́ ẹyọ kan. Ó sì sọ pé: "Fà á lé mi lọ́wọ́. Ó sì borí mi nínú ọ̀rọ̀
- (Ànábì Dāwūd) sọ pé: "Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-àlà lórí apá kan àfi àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n. (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni- afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu). òǹkà ìyàwó wọn lè pọ̀ ní òǹkà kì í ṣe ní ti ìgbádùn adùn-ara bí kò ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ kọ́ Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ẹ̀kọ́ ìgbẹ́jọ́ nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ fi ṣe adájọ́ láààrin àwọn ìjọ rẹ̀. Àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn ni àṣíṣe t’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Èyí náà sì ni ohun tí ó tọrọ àforíjìn Ọlọ́hun fún
- Nítorí náà, A ṣàforíjìn ìyẹn fún un. Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un lọ́dọ̀ Wa
- (Ànábì) Dāwūd, dájúdájú Àwa ṣe ọ́ ní àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, dájọ́ láààrin àwọn ènìyà́n pẹ̀lú òdodo. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú nítorí kí ó má baà ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Dájúdájú àwọn t’ó ń sọnù kúrò nínú ẹ̀sìn Allāhu, ìyà líle wà fún wọn nítorí pé wọ́n gbàgbé Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́
- A kò ṣẹ̀dá sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì pẹ̀lú irọ́. (Irọ́), ìyẹn ni èrò àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Iná
- Ṣé kí Á ṣe àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere bí (A ó ti ṣe) àwọn òbìlẹ̀jẹ́ lórí ilẹ̀? Tàbí ṣé kí Á ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Mi bí A ó ti ṣe) àwọn aṣebi
- (Èyí ni) Tírà ìbùkún tí A sọ̀ kalẹ̀ fún ọ nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa àwọn āyah rẹ̀ àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí
- A fi (Ànábì) Sulaemọ̄n ta (Ànábì) Dāwūd lọ́rẹ. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sọ́dọ̀ (Allāhu) ni (nípa ìronúpìwàdà)
- (Rántí) nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹṣin akáwọ́ọ̀jà-lérí asárétete wá bá a ní ìrọ̀lẹ́
- ó sọ pé: "Dájúdájú èmi fẹ́ràn ìfẹ́ ohun rere (ìyẹn, àwọn ẹṣin náà) dípò ìrántí Olúwa Mi (ìyẹn, ìrun ‘Asr) títí òòrùn fi wọ̀
- Ẹ dá wọn padà sọ́dọ̀ mi. "Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi idà gé wọn ní ẹsẹ̀ àti ní ọrùn
- Dájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà). Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ìyàwó t’ó tó ọgọ́rùn-ún lábẹ́ òfin ẹ̀tọ́ (ìyẹn ni pé Allāhu s.w.t. l’Ó ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún un). Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sì fi Allāhu búra ní ọjọ́ kan pé kì í ṣe ara òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni àwọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n wà. Báwo wá ni ó ṣe máa jẹ́ pé nípasẹ̀ òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ni àwọ̀ rẹ̀ fi máa kúrò lára rẹ̀ sí ara èṣù àlùjànnú nígbà tí Ànábì Sulaemọ̄n kì í ṣe òpìdán? Ànábì Sulaemọ̄n kò sì fi òrùka jọba áḿbọ̀sìbọ́sí pé nígbà tí kò bá sí òrùka rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ l’ó máa fún ẹlòmíìràn ní àyè láti di ọba! Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:102. W-Allāhu ’a‘lam
- Ó sọ pé: "Olúwa mi, forí jìn mí. Kí O sì ta mí ní ọrẹ ìjọba kan èyí tí kò níí tọ́ sí ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn mi. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Ọlọ́rẹ
- Nítorí náà, A tẹ atẹ́gùn ba fún un. Ó ń fẹ́ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn síbi tí ó bá fẹ́
- Àti àwọn èṣù àlùjànnú; gbogbo àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn awakùsà (ni A tẹ̀ ba fún un)
- Àti àwọn (àlùjànnú) mìíràn tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mọ́lẹ̀ (A tẹ̀ wọ́n ba fún un)
- Èyí ni ọrẹ Wa. Nítorí náà, fi tọrẹ tàbí kí ó mú un dání láì la ìṣírò lọ (lọ́run)
- Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un ní ọ̀dọ̀ Wa
- Ṣèrántí ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ayyūb. Nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ (pé): "Dájúdájú Èṣù ti kó ìnira (àìsàn) àti ìyà bá mi
- (Mọlāika sọ fún un pé): "Fi ẹsẹ̀ rẹ janlẹ̀. Èyí ni omi ìwẹ̀ tútù àti omi mímu (fún ìwòsàn rẹ)
- A sì ta á lọ́rẹ àwọn ará ilé rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn. (Ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè
- Fi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ. Dájúdájú Àwa rí (’Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà)
- Ṣèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára, olùríran (nípa ẹ̀sìn)
- Dájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan; ìrántí Ilé Ìkẹ́yìn
- Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa
- Ṣèrántí (àwọn Ànábì) ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘ àti Thul-Kifl. Ìkọ̀ọ̀kan wọn wà nínú àwọn ẹni rere jùlọ
- Èyí ni ìrántí. Àti pé dájúdájú àbọ̀ rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
- Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére (ni). Wọ́n sì máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn
- Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú nínú rẹ̀. Wọn yóò máa bèèrè fún àwọn èso púpọ̀ àti ohun mímu nínú rẹ̀
- Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, tí ọjọ́ orí wọn kò jura wọn lọ yó sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn
- Èyí ni ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín fún Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́
- Dájúdájú èyí ni arísìkí Wa. Kò sì níí tán
- Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Àti pé dájúdájú àbọ̀ burúkú ni ti àwọn alágbèéré (sí Allāhu)
- Iná Jahanamọ ni wọn yó wọ̀. Ó sì burú ní ibùgbé
- Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, kí wọ́n tọ́ ọ wò; omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀
- Oríṣiríṣi (ìyà) mìíràn bí irú rẹ̀ (tún wà fún wọn)
- Èyí ni ìjọ kan t’ó máa wọ inú Iná pẹ̀lú yín. (Àwọn aṣíwájú nínú Iná sì máa wí pé:) "Kò sí máawolẹ̀-máarọra fún wọn." Dájúdájú wọn yóò wọ inú Iná ni
- (Àwọn ọmọlẹ́yìn nínú Iná) máa wí pé: "Rárá, ẹ̀yin náà kò sí máawolẹ̀-máarọra fun yín. Ẹ̀yin l’ẹ pè wá síbi èyí (t’ó bí Iná)." Ó sì burú ní ibùgbé
- Wọ́n (tún) wí pé: "Olúwa wa, ẹni tí ó pè wá (síbi ìyà) yìí, ṣe àlékún àdìpèlé ìyà fún un nínú Iná
- Wọ́n tún wí pé: "Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wa tí a ò rí àwọn ọkùnrin kan, àwọn tí à ń kà mọ́ àwọn ẹni burúkú
- Ṣèbí a fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí àwọn ojú ti fò wọ́n ni (l’a ò fi rí wọn nínú Iná)
- Dájúdájú ìyẹn, àríyànjiyàn àwọn èrò inú Iná, òdodo mà ni
- Sọ pé: "Èmi ni olùkìlọ̀. Àti pé kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àyàfi Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí
- Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì, Alágbára, Aláforíjìn
- Sọ pé: "(al-Ƙur’ān) ni ìró ńlá
- Ẹ̀yin sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀
- Èmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé
- Kí ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi bí kò ṣe pé èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé
- (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: "Dájúdájú Èmi yóò dá abara kan láti inú ẹrùpẹ̀
- Nígbà tí Mo bá ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ tán, tí Mo sì fẹ́ nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí Mo dá sínú rẹ̀, nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni
- Gbogbo àwọn mọlāika pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i
- Àyàfi ’Iblīs, tí ó ṣègbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́
- (Allāhu) sọ pé: "’Iblīs, kí l’ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí ohun tí Mo fi ọwọ́ Mi méjèèjì dá? Ṣé o ṣègbéraga ni tàbí o wà nínú àwọn ẹni gíga
- Ó wí pé: "Èmi lóore jùlọ sí òun; O dá èmi láti ara iná. O sì dá òun láti ara erùpẹ̀ amọ̀
- (Allāhu) sọ pé: "Jáde kúrò nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) nítorí pé dájúdájú ìwọ ni ẹni ẹ̀kọ̀
- Àti pé dájúdájú ègún Mi yóò wà lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san
- (Èṣù) wí pé: "Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí Wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde
- (Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn tí wọ́n máa lọ́ lára
- títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ
- (Èṣù) wí pé: "Mo fi agbára Rẹ búra, dájúdájú èmi yóò kó gbogbo wọn sínú ìṣìnà
- àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn ẹni ẹ̀ṣà nínú wọn
- (Allāhu) sọ pé: "Òdodo (ni ìbúra Mi), òdodo sì ni Èmi ń sọ, (pé)
- dájúdájú Mo máa fi ìwọ àti gbogbo àwọn t’ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn kún inú iná Jahanamọ
- Sọ pé: "Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Èmi kò sì sí nínú àwọn onítàn-àròsọ
- Kí ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá
- Àti pé dájúdájú ẹ máa mọ ìró rẹ̀ (sí òdodo) láìpẹ́