37.Those drawn up in Ranks

  1. (Allāhu búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika olùtò-lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tààrà
  2. àti àwọn mọlāika t’ó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà
  3. àti àwọn mọlāika òǹké-tírà ìrántí
  4. Dájúdájú Ọlọ́hun yín, Ọ̀kan ṣoṣo ni
  5. Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn
  6. Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
  7. àti ìṣọ́ níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun
  8. (Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika t’ó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀). (Àwọn mọlāika) yó sì máa ku (àwọn èṣù) lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀)
  9. Wọ́n ń lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn
  10. (Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní kíkún) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná t’ó máa jó o tẹ̀lé e
  11. Bi wọ́n léèrè wò pé ṣé àwọn ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (ènìyàn) tí A dá? Dájúdájú Àwa dá wọn láti ara erùpẹ̀ t’ó lẹ̀ mọ́ra wọn
  12. Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́
  13. Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí
  14. Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́
  15. Wọ́n sì wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé
  16. Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni
  17. Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́
  18. Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ
  19. Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn
  20. Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san
  21. Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè nírọ́
  22. Ẹ kó àwọn t’ó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
  23. lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm
  24. Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè
  25. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ranra yín lọ́wọ́
  26. Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni
  27. Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè
  28. (Àwọn ènìyàn) wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà)
  29. (Àwọn àlùjànnú) wí pé: "Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  30. Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu àlà
  31. Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò
  32. Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà
  33. Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà
  34. Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
  35. Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.", wọn yóò máa ṣègbéraga
  36. Wọ́n sì ń wí pé: "Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan
  37. Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà
  38. Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò
  39. A ò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
  40. Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
  41. Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀
  42. àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
  43. nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
  44. Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn
  45. Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ káà kiri ọ̀dọ̀ wọn
  46. Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn t’ó máa mu ún
  47. Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀
  48. Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn
  49. Wọ́n dà bí tinú ẹyin. ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run
  50. Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè
  51. Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
  52. tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde
  53. Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
  54. Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)
  55. Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm
  56. Ó (sì) sọ pé: "Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán
  57. Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná
  58. Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí
  59. Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà
  60. Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá
  61. Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ
  62. Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)
  63. Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí
  64. Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm
  65. Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù
  66. Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, wọn yóò fi kún inú wọn bámúbámú
  67. Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu n̄ǹkan mímu àwọyúnwẹ̀jẹ̀ gbígbóná lé e lórí
  68. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm
  69. Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà
  70. Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn
  71. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn
  72. Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn
  73. Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí
  74. Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
  75. Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè
  76. A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá
  77. A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀
  78. A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
  79. Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá
  80. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
  81. Dájúdájú òun wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  82. Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami
  83. Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀
  84. (Ẹ rántí) nígbà tí òun náà dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́
  85. (Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún
  86. Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu
  87. Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
  88. Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ gan-an
  89. Ó sì sọ pé: "Dájúdájú ó rẹ̀ mí
  90. Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ
  91. Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni
  92. Kí ni ó ṣe yín tí ẹ ò sọ̀rọ̀
  93. Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú)
  94. (Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́
  95. Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni
  96. Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
  97. Wọ́n wí pé: "Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná
  98. Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ
  99. Ó sọ pé: "Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀)
  100. Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere
  101. A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin aláfaradà
  102. Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: "Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́
  103. Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀
  104. A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm
  105. o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
  106. Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé
  107. A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀
  108. A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
  109. Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm
  110. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
  111. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  112. A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere
  113. Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (t’ó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì
  114. Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn
  115. A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá
  116. A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn)
  117. A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà t’ó yanjú
  118. A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà
  119. A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
  120. Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn
  121. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
  122. Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  123. Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́
  124. (Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni
  125. Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām 6:62) olùdájọ́ aláàánú ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà àdámọ́ owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn t’ó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú
  126. (ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́
  127. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná
  128. Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
  129. A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
  130. Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās
  131. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
  132. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  133. Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́
  134. (Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là
  135. Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́)
  136. Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run
  137. Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
  138. àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni
  139. Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́
  140. (Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́
  141. Ó sì bá wọn muje pọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí aje ṣí mọ́ lórí
  142. Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi
  143. Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu
  144. dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde
  145. Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera
  146. A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó
  147. A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i
  148. Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀
  149. Bi wọ́n léèrè wò pé: "Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin
  150. Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí
  151. Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé
  152. Allāhu bímọ." Dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n
  153. Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni
  154. Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí
  155. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni
  156. Tàbí ẹ ní ẹ̀rí t’ó yanjú lọ́wọ́ ni
  157. Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo
  158. Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni
  159. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)
  160. Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
  161. Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu)
  162. ẹ ò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
  163. àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm
  164. Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀
  165. Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
  166. Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu)
  167. Wọ́n kúkú ń wí pé
  168. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́
  169. dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
  170. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀
  171. Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́
  172. Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún
  173. Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí
  174. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀
  175. Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò
  176. Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú
  177. Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí agboolé wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún
  178. Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná
  179. Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò
  180. Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)
  181. Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
  182. Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá