Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga
Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn kúrò lórí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn
Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere)
Ǹjẹ́ ẹni t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni t’ó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba
Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere)
Ní ti àwọn t’ó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè nírọ́ wò.”
Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí t’ó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí ó ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀). A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl
Àti pé A ṣe àwọn aṣíwájú kan nínú wọn ní afinimọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù. Wọ́n sì ń ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa
Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí
Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni
Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ wọn kò níí ṣàǹfààní fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nínú Allāhu). A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).”