27.The Ant
- Tọ̄ sīn. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah al-Ƙur’ān àti (àwọn āyah) Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá
- (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
- àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn
- Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti ṣe àwọn iṣẹ́ (aburú ọwọ́) wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, Nítorí náà, wọn yó sì máa pa rìdàrìdà
- Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìyà burúkú wà fún. Àwọn sì ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn
- Dájúdájú ò ń gba al-Ƙur’ān làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀
- (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo rí iná kan. Mo sì máa lọ mú ìró kan wá fun yín láti ibẹ̀, tàbí kí n̄g mú ògúnná kan t’ó ń tanná wá fun yín nítorí kí ẹ lè yẹ́ná
- Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pèpè pé kí ìbùkún máa bẹ fún ẹni tí ó wà níbi iná náà àti ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Mímọ́ sì ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá
- Mūsā, dájúdájú Èmi ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
- Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀. (Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.) Àmọ́ nígbà tí ó rí i t’ó ń yíra padà bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìn dà, ó ń sá lọ. Kò sì padà. (Allāhu sọ pé:) Mūsā, má ṣe páyà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kì í páyà lọ́dọ̀ Mi
- Àyàfi ẹni tí ó bá ṣàbòsí, lẹ́yìn náà tí ó yí i padà sí rere lẹ́yìn aburú. Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
- Ti ọwọ́ rẹ bọ (abíyá láti ibi) ọrùn ẹ̀wù rẹ. Ó sì máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe ti aburú. (Èyí wà) nínú àwọn àmì mẹ́sàn-án (tí o máa mú lọ) bá Fir‘aon àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́
- Nígbà tí àwọn àmì Wa, t’ó fojú hàn kedere, sì dé bá wọn, wọ́n wí pé: “Èyí ni idán pọ́nńbélé.”
- Wọ́n takò ó pẹ̀lú àbòsí àti ìgbéraga, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú pé òdodo ni. Nítorí náà, wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ti rí
- Dájúdájú A fún (Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n ní ìmọ̀. Àwọn méjèèjì sì sọ pé: "Ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ẹni tí Ó fún wa ní oore àjùlọ lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
- (Ànábì) Sulaemọ̄n sì jogún (Ànábì) Dāwūd. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi ohùn ẹyẹ mọ̀ wá. Wọ́n sì fún wa ní gbogbo n̄ǹkan. Dájúdájú èyí, òhun ni oore àjùlọ pọ́nńbélé
- A sì kó jọ fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú àlùjànnú, ènìyàn àti ẹyẹ. A sì ń kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn
- títí wọ́n fi dé àfonífojì àwọn àwúrèbe. Àwúrèbe kan sì wí pé: "Ẹ̀yin àwúrèbe, ẹ wọ inú ilé yín lọ, kí (Ànábì) Sulaemọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ má baà tẹ̀ yín rẹ́ mọ́lẹ̀. Wọn kò sì níí fura
- Nígbà náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) rẹ́rìn-ín músẹ́, ẹ̀rín pa á nítorí ọ̀rọ̀ (àwúrèbe náà). Ó sọ pé: “Olúwa mi, fi mọ̀ mí bí mo ṣe máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí O fi ṣe ìdẹ̀ra fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì. (Fi mọ̀ mí) bí mo ṣe máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Pẹ̀lú àánú Rẹ fi mí sáààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni rere.”
- Ó ṣàbẹ̀wò àwọn ẹyẹ, ó sì sọ pé: “Nítorí kí ni mi ò ṣe rí ẹyẹ hudhuda? Àbí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí kò wá ni
- Dájúdájú mo máa jẹ ẹ́ níyà líle, tàbí kí n̄g dúńbú rẹ̀, tàbí kí ó mú ẹ̀rí t’ó yanjú wá fún mi.”
- (Ànábì Sulaemọ̄n) kò dúró pẹ́ (títí ó fi dé), ó sì wí pé: "Mo mọ n̄ǹkan tí o ò mọ̀. Mo sì mú ìró kan t’ó dájú wá bá ọ láti ìlú Saba’i
- Dájúdájú èmi bá obìnrin kan (níbẹ̀), t’ó ń ṣe ìjọba lé wọn lórí. Wọ́n fún un ní gbogbo n̄ǹkan. Ó sì ní ìtẹ́ ńlá kan
- Mo sì bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún òòrùn lẹ́yìn Allāhu. Èṣù sì ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (òdodo). Nítorí náà, wọn kò sì mọ̀nà
- láti forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni t’Ó ń mú ọrọ̀ t’ó pamọ́ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ jáde, Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn
- Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ ńlá
- Ó sọ pé: "A máa wòye bóyá òdodo l’o sọ ni tàbí o wà nínú àwọn òpùrọ́
- Mú ìwé mi yìí lọ, kí o jù ú sí wọn. Lẹ́yìn náà, kí o takété sí wọn, kí o sì wo ohun tí wọn yóò dá padà (ní èsì)
- (Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, dájúdájú wọ́n ti ju ìwé alápọ̀n-ọ́nlé kan sí mi
- Dájúdájú ó wá láti ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n. Dájúdájú ó (sọ pé) “Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run
- Kí ẹ má ṣègbéraga sí mi, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi (láti di) mùsùlùmí.”
- (Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ gbà mí ní ìmọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì í gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan títí ẹ máa fi jẹ́rìí sí i.”
- Wọ́n wí pé: “Alágbára ni àwa. Akọni ogun sì tún ni wá. Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọ̀rọ̀ wà. Nítorí náà, wòye sí ohun tí o máa pa láṣẹ.”
- (Bilƙīs) wí pé: “Dájúdájú àwọn ọba, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ìlú kan, wọn yóò bà á jẹ́. Wọn yó sì sọ àwọn ẹni abiyì ibẹ̀ di ẹni yẹpẹrẹ. Báyẹn ni wọ́n máa ń ṣe
- Dájúdájú mo máa fi ẹ̀bùn kan ránṣẹ́ sí wọn. Mo sì máa wòye sí ohun tí àwọn ìránṣẹ́ yóò mú padà (ní èsì).”
- Nígbà tí (ìránṣẹ́) dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n, ó sọ pé: “Ṣé ẹ máa fi owó ràn mí lọ́wọ́ ni? Ohun tí Allāhu fún mi lóore jùlọ sí ohun tí ẹ fún mi. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin tún ń yọ̀ lórí ẹ̀bùn yín
- Padà sí ọ̀dọ̀ wọn. Dájúdájú à ń bọ̀ wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lè kojú rẹ̀. Dájúdájú a máa mú wọn jáde kúrò nínú (ìlú wọn) ní ẹni àbùkù. Wọn yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.”
- (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èwo nínú yín l’ó máa gbé ìtẹ́ (Bilƙīs) wá bá mi, ṣíwájú kí wọ́n tó wá bá mi (láti di) mùsùlùmí.”
- ‘Ifrīt nínú àwọn àlùjànnú sọ pé: “Èmi yóò gbe wá fún ọ ṣíwájú kí o tó dìde kúrò ní àyè rẹ. Dájúdájú èmi ni alágbára, olùfọkàntán lórí rẹ̀.”
- Ẹni tí ìmọ̀ kan láti inú tírà wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò gbé e wá fún ọ ṣíwájú kí o tó ṣẹ́jú.” Nígbà tí ó rí i tí ó dé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí wà nínú oore àjùlọ Olúwa mi, láti fi dán mi wò bóyá mo máa dúpẹ́ tàbí mo máa ṣàì moore. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́ (fún Allāhu), ó dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàìmoore, dájúdájú Olúwa mi ni Ọlọ́rọ̀, Alápọ̀n-ọ́nlé.”
- Ó sọ pé: “Ẹ ṣe ìyípadà ìrísí ìtẹ́ rẹ̀ fún un, kí á wò ó bóyá ó máa dá a mọ̀ tàbí ó máa wà nínú àwọn tí kò níí dá a mọ̀.”
- Nígbà tí (Bilƙīs) dé, wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé bí ìtẹ́ rẹ ṣe rí nìyí?” Ó wí pé: "Ó dà bí ẹni pé òhun ni." (Ànábì Sulaemọ̄n sì sọ pé): “Wọ́n ti fún wa ní ìmọ̀ ṣíwájú Bilƙīs. A sì jẹ́ mùsùlùmí.”
- Ohun t’ó ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu sì ṣẹ́rí rẹ̀ (kúrò níbi ìjọ́sìn fún Allāhu). Dájúdájú ó wà nínú ìjọ aláìgbàgbọ́
- Wọ́n sọ fún un pé: “Wọ inú ààfin.” Nígbà tí ó rí i, ó ṣe bí ibúdò ni. Ó sì ká aṣọ kúrò ní ojúgun rẹ̀ méjèèjì. (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Dájúdájú ààfin tí a ṣe rigidin pẹ̀lú díńgí ni.” (Bilƙīs) sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú mo ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Mo sì di mùsùlùmí pẹ̀lú (Ànábì) Sulaemọ̄n, fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá
- Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí ìjọ Thamūd. (A rán) arákùnrin wọn, Sọ̄lih (níṣẹ́ sí wọn), pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu." Nígbà náà ni wọ́n pín sí ìjọ méjì, t’ó ń bára wọn jiyàn
- Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá (ìyà) aburú pẹ̀lú ìkánjú ṣíwájú (ohun) rere (t’ó yẹ kí ẹ mú ṣe níṣẹ́)? Ẹ ò ṣe tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu nítorí kí Wọ́n lè ṣàánú yín?”
- Wọ́n wí pé: “A rí àmì aburú láti ọ̀dọ̀ rẹ àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ.” (Ànábì Sọ̄lih) sọ pé: “Àmì aburú yín wà (nínú kádàrá yín) lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sì rí bí ẹ ṣe rò ó àmọ́ ìjọ aládàn-ánwò ni yín ni.”
- Àwọn ènìyàn mẹ́sàn-án kan sì wà nínú ìlú, tí wọ́n ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere
- Wọ́n wí (fúnra wọn) pé: “Kí á dìjọ fí Allāhu búra pé dájúdájú a máa pa òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní òru. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa sọ fún ẹbí rẹ̀ pé ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣojú wa. Dájúdájú olódodo sì ni àwa.”
- Wọ́n déte gan-an, Àwa náà sì déte gan-an, wọn kò sì fura
- Wo bí àtubọ̀tán ète wọn ti rí. Dájúdájú A pa àwọn àti ìjọ wọn run pátápátá
- Nítorí náà, ìwọ̀nyẹn ni ilé wọn. Ó tí di ilé ahoro nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó nímọ̀
- A gba àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo là, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu)
- (A tún fi iṣẹ́ ìmísí rán Ànábì) Lūt. (Rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé iṣẹ́ aburú ni ẹ óò máa ṣe ni, ẹ sì ríran
- Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín ni) dípò àwọn obìnrin? Àní sẹ́, òpè ènìyàn ni yín
- Kò sí ohun kan tí ìjọ rẹ̀ fọ̀ ní èsì tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ lé àwọn ènìyàn Lūt jáde kúrò nínú ìlú yín. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn t’ó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”
- Nítorí náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ ọ́ pé ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun
- A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú
- Sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Kí àlàáfíà máa bá àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tí Ó ṣà lẹ́ṣà. Ṣé Allāhu l’Ó lóore jùlọ ni tàbí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀
- (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó lóore jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sọ omi kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀, tí A sì fi omi náà hu àwọn ọgbà oko tí ó dára jáde? Kò sì sí agbára fun yín láti mu igi rẹ̀ hù jáde. Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Rárá, ìjọ t’ó ń ṣẹbọ sí Allāhu ni wọ́n ni
- (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ibùgbé, tí Ó fi àwọn odò sáààrin rẹ̀, tí Ó fi àwọn àpáta t’ó dúró ṣinṣin sínú ilẹ̀, tí Ó sì fi gàgá sáààrin ibúdò méjèèjì? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀
- (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń jẹ́pè ẹni tí ara ń ni nígbà tí ó bá pè É, tí Ó sì máa gbé aburú kúrò fún un, tí Ó sì ń ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Díẹ̀ ni ohun tí ẹ̀ ń lò nínú ìrántí
- (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń tọ yín sọ́nà nínú àwọn òkùnkùn orí ilẹ̀ àti inú ibúdò, tí Ó tún ń fi atẹ́gùn ránṣẹ́ ní ìró ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Allāhu ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I
- (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí Ó máa dá a padà (lẹ́yìn ikú), tí Ó sì ń pèsè fun yín láti sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: "Ẹ mú ẹ̀rí yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo
- Sọ pé: “Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àfi Allāhu. Àti pé wọn kò sì mọ àsìkò wo ni A máa gbé àwọn òkú dìde.”
- Bẹ́ẹ̀ ni, ní ọ̀run ni ìmọ̀ wọn máa tó mọ Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (lọ́ràn). Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ (báyìí). Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti fọ́nú-fọ́ra nípa rẹ̀
- Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé nígbà tí àwa àti àwọn bàbá wa bá ti di erùpẹ̀, ṣé (nígbà náà ni) wọn yóò mú wa jáde
- Wọ́n kúkú tí ṣe àdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
- Sọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí.”
- Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń dá ní ète kó ìnira bá ọ
- Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
- Sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé apá kan ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ti súnmọ́ yín tán.”
- Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Ọlọ́lá lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kì í dúpẹ́ (fún Un)
- Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó kúkú mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń gbé pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀
- Àti pé kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó hàn kedere
- Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí yóò máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí
- Àti pé dájúdájú ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
- Dájúdájú Olúwa rẹ máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú ìdájọ́ Rẹ̀. Òun ni Alágbára, Onímọ̀
- Nítorí náà, gbáralé Allāhu. Dájúdájú ìwọ wà lórí òdodo pọ́nńbélé
- Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ
- Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́ nítorí pé àwọn ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu
- Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà bá kò lé wọn lórí, A máa mú ẹranko kan jáde fún wọn láti inú ilẹ̀, tí ó máa bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú àwọn ènìyàn kì í nímọ̀ àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.”
- Àti pé (rántí) ọjọ́ tí A óò kó ìjọ kan jọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan nínú àwọn t’ó ń pe àwọn āyah Wa nírọ́. A ó sì kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn
- Títí (di) ìgbà tí wọ́n bá dé (tán), (Allāhu) yóò sọ pé: "Ṣé ẹ pe àwọn āyah Mi nírọ́, tí ẹ̀yin kò sì ní ìmọ̀ kan nípa rẹ̀ (tí ẹ lè fi já a nírọ́)? Tàbí kí ni ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ (nílé ayé)
- Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀
- Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’A dá òru nítorí kí wọ́n lè sinmi nínú rẹ̀, (A sì dá) ọ̀sán (nítorí kí wọ́n lè) ríran? Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo
- (Rántí) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo, gbogbo ẹni tí ó wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ yó sì jáyà àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Gbogbo ẹ̀dá l’ó sì máa yẹpẹrẹ wá bá Allāhu
- O sì máa rí àwọn àpáta, tí o lérò pé n̄ǹkan gbagidi t’ó dúró sojú kan náà ni, tí ó máa rin ìrìn ẹ̀ṣújò. (Ìyẹn jẹ́) iṣẹ́ Allāhu, Ẹni tí Ó ṣe gbogbo n̄ǹkan ní dáadáa. Dájúdájú Ó mọ ìkọ̀kọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
- Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú iṣẹ́ rere wá, tirẹ̀ ni rere t’ó lóore jùlọ sí èyí t’ó mú wá. Àwọn sì ni olùfàyàbalẹ̀ nínú ìjáyà ọjọ́ yẹn
- Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú (iṣẹ́) aburú wá, A sì máa da ojú wọn bolẹ̀ nínú Iná. Ǹjẹ́ A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
- Ohun tí wọ́n pa mí ní àṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Olúwa Ìlú yìí, Ẹni tí Ó ṣe é ní àyè ọ̀wọ̀. TiRẹ̀ sì ni gbogbo n̄ǹkan. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn mùsùlùmí
- Àti pé kí n̄g máa ké al-Ƙur’ān. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkìlọ̀.”
- Sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu.” (Allāhu) yóò fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ẹ̀yin yó sì mọ̀ wọ́n. Olúwa rẹ kò sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́