26.The Poets

  1. Tọ̄ sīn mīm
  2. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá
  3. Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  4. Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un
  5. Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀
  6. Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn
  7. Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀
  8. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  9. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  10. (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: "Lọ bá ìjọ alábòsí
  11. ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé 'Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni
  12. Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́
  13. Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn
  14. Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí
  15. (Allāhu) sọ pé: "Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín)
  16. Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: 'Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  17. (À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ
  18. (Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ
  19. O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”
  20. (Ànábì Mūsā) sọ pé: "Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláìmọ̀kan ni
  21. Mo sì sá fun yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Nítorí náà, Allāhu ti ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́
  22. Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́)
  23. Fir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
  24. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni)
  25. (Fir‘aon) wí fún àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (t’ó ń sọ ni)?”
  26. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
  27. (Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”
  28. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”
  29. (Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”
  30. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan t’ó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”
  31. (Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”
  32. Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé
  33. Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran
  34. (Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa
  35. Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”
  36. Wọ́n wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú
  37. (pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ
  38. Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀
  39. Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: "Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí
  40. Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí
  41. Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”
  42. (Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”
  43. (Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”
  44. Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”
  45. Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló
  46. Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu)
  47. Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  48. Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn
  49. Fir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”
  50. (Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa
  51. Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”
  52. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé) dájúdájú wọn yóò lépa yín.”
  53. Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé)
  54. Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n
  55. Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun t’ó ń bí wa nínú
  56. Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura
  57. Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi
  58. àti àwọn àpótí-ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé
  59. Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl
  60. Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ
  61. Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”
  62. (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”
  63. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà á). Ó sì pín (sí ọ̀nà méjìlá). Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá
  64. A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn
  65. A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá
  66. Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami)
  67. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  68. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  69. Ka ìròyìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn
  70. Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”
  71. Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”
  72. (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n
  73. Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní oore tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”
  74. Wọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa, tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”
  75. (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún
  76. ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ìṣaájú
  77. Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  78. (Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí
  79. Ẹni t’Ó ń fún mi ní jíjẹ, t’Ó ń fún mi ní mímu
  80. Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn
  81. Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè
  82. Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san
  83. Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere
  84. Jẹ́ kí àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn (mi) máa sọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú dáadáa
  85. Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra
  86. Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà
  87. Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde
  88. Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní
  89. Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́
  90. A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
  91. Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà
  92. wọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”
  93. (N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́
  94. Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn sínú Iná; àwọn àti èṣù wọn
  95. àti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá
  96. (Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé
  97. A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
  98. nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  99. Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (èṣù) ẹlẹ́ṣẹ̀
  100. Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa
  101. Kò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa)
  102. Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  103. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  104. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  105. Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́
  106. Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni
  107. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín
  108. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
  109. Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  110. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”
  111. Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”
  112. Ó sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi)
  113. Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura
  114. Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù
  115. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
  116. Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”
  117. Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́
  118. Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
  119. A la òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́
  120. Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn t’ó ṣẹ́kù rì sínú omi
  121. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  122. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  123. Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́
  124. Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni
  125. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín
  126. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
  127. Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  128. Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀
  129. Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí)
  130. Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú
  131. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
  132. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀
  133. Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ
  134. àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi
  135. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fun yín.”
  136. Wọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o kìlọ̀ fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn olùkìlọ̀
  137. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́
  138. Wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”
  139. Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  140. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  141. Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́
  142. Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni
  143. Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín
  144. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
  145. Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  146. Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀
  147. nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi
  148. àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ tutù
  149. Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́
  150. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
  151. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn aláṣejù
  152. àwọn t’ó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”
  153. Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì
  154. Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
  155. Ó sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀
  156. Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”
  157. Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀
  158. Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  159. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  160. Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́
  161. Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni
  162. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín
  163. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
  164. Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  165. Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)
  166. Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fun yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”
  167. Wọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”
  168. Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùbínú sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín
  169. Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú)
  170. Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá
  171. Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́)
  172. Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run
  173. A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú
  174. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  175. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  176. Àwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́
  177. Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni
  178. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín
  179. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
  180. Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  181. Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn olùdóṣùwọ̀nkù
  182. Ẹ fi ìwọ̀n t’ó tọ́ wọn n̄ǹkan
  183. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe hùwà aburú lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́
  184. Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ìran àkọ́kọ́.”
  185. Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì
  186. Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a ò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé ó wà nínú àwọn òpùrọ́
  187. Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
  188. Ó sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
  189. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá
  190. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
  191. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  192. Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  193. Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀
  194. sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀
  195. pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé
  196. Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) ti wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́
  197. Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)
  198. Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni
  199. tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo
  200. Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
  201. Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro
  202. (Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura
  203. Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí
  204. Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú
  205. Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ
  206. Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn dé bá wọn
  207. Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀
  208. A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀
  209. Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí
  210. Kì í ṣe àwọn èṣù ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀
  211. Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀
  212. Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀)
  213. Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà
  214. Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ, t’ó súnmọ́ jùlọ
  215. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn t’ó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo
  216. Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”
  217. Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  218. Ẹni t’Ó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)
  219. àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀
  220. Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀
  221. Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn èṣù ń sọ̀kalẹ̀ wá bá
  222. Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀
  223. (Àwọn èṣù) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́
  224. Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn
  225. Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni
  226. Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe
  227. Àfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí