111.The Palm Fibre

  1. Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò
  2. Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà)
  3. Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò
  4. Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná)
  5. Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná)