110.Divine Support

  1. Nígbà tí àrànṣe Allāhu (lórí ọ̀tá ẹ̀sìn) àti ṣíṣí ìlú (Mọ́kkah) bá ṣẹlẹ̀
  2. tí o sì rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wọnú ẹ̀sìn Allāhu níjọníjọ
  3. nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ. Kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà