107.Almsgiving

  1. Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san nírọ́
  2. Ìyẹn ni ẹni t’ó ń lé ọmọ-òrukàn dànù
  3. Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù
  4. Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) t’ó ń kírun; kò túmọ̀ sí “ohun t’ó ń run ènìyàn”. Àmọ́ ìtúmọ̀ “ìrun” ni “ohun t’ó ń run ẹ̀ṣẹ̀ olùkírun” nítorí pé tí olùkírun bá ti ṣe àlùwàlá ni ó ti ṣan gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí ó ti fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ ṣe ṣíwájú. Bákan náà
  5. àwọn t’ó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀
  6. àwọn t’ó ń ṣe ṣekárími
  7. àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn)