106.Quraysh

  1. (Ìkẹ́ ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún ìdílé Ƙuraeṣ láti wà papọ̀ nínú ààbò
  2. (Ìkẹ́ ni sẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún wọn láti wà papọ̀ nínú ààbò lórí ìrìn-àjò ní ìgbà òtútù àti ìgbà ooru
  3. Nítorí náà, kí wọ́n jọ́sìn fún Olúwa Ilé (Ka‘bah) yìí
  4. Ẹni tí Ó fún wọn ní jíjẹ (ní àsìkò) ebi. Ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nínú ìpáyà