105.The Elephant

  1. Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ìjọ elérin ni
  2. Ṣé kò sọ ète wọn di òfo bí
  3. Ó sì rán àwọn ẹyẹ níkọ̀níkọ̀ sí wọn
  4. Wọ́n ń jù wọ́n ní òkúta amọ̀ (t’ó ti gbaná sára)
  5. Ó sì sọ wọ́n di bíi èrúnrún koríko àjẹkù gbígbẹ