104.The Traducer

  1. Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni
  2. ẹni tí ó kó owó jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fẹ́sìn)
  3. Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé)
  4. Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni
  5. Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Hutọmọh
  6. (Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (t’ó ń jò geregere)
  7. èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ
  8. Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá
  9. (Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná)