102.Competition

  1. Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín
  2. títí ẹ fi wọ inú sàréè
  3. Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀
  4. Lẹ́yìn náà, ní òdodo láìpẹ́ ẹ máa mọ̀
  5. Bẹ́ẹ̀ ni, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀)
  6. Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm
  7. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa rí i ní àrídájú
  8. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí)